28. Àwọn ìdílé akọrin bá kó ara wọn jọ láti gbogbo agbègbè Jerusalẹmu ati láti àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká Netofati,
29. bákan náà ni láti Betigiligali ati láti ẹkùn Geba, ati Asimafeti, nítorí pé àwọn akọrin kọ́ ìletò fún ara wọn ní agbègbè Jerusalẹmu.
30. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àwọn eniyan ati àwọn bodè ati odi ìlú náà.
31. Mo bá kó àwọn ìjòyè Juda lọ sórí odi náà, mo sì yan ọ̀wọ́ meji pataki tí wọ́n ṣe ìdúpẹ́ tí wọ́n sì tò kọjá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.Àwọn kan tò lọ ní apá ọ̀tún odi náà lọ sí Ẹnubodè Ààtàn,
32. lẹ́yìn náà, Hoṣaaya ati ìdajì àwọn ìjòyè Juda tẹ̀lé wọn,
33. Ati Asaraya, Ẹsira ati Meṣulamu,
34. Juda, Bẹnjamini ati Ṣemaaya, ati Jeremaya.
35. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ alufaa tẹ̀lé wọn pẹlu fèrè.Àwọn nìwọ̀nyí: Sakaraya, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mikaaya, ọmọ Sakuri, ọmọ Asafu,