5. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maaseaya, ọmọ Baruku, ọmọ Kolihose, ọmọ Hasaya, ọmọ Adaya, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sakaraya, ọmọ ará Ṣilo.
6. Gbogbo àwọn ọmọ Peresi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu jẹ́ akọni, wọ́n jẹ́ ọtalenirinwo ó lé mẹjọ (468).
7. Àwọn ọmọ Bẹnjamini ni: Salu ọmọ Meṣulamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaaya, ọmọ Kolaya, ọmọ Maaseaya, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaya.
8. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Gabai ati Salai. Àpapọ̀ gbogbo àwọn ọmọ Bẹnjamini wá jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mejidinlọgbọn (928).
9. Joẹli ọmọ Sikiri ni alabojuto wọn, Juda ọmọ Hasenua ni igbákejì rẹ̀ ní ìlú náà.
10. Àwọn alufaa ni: Jedaaya ọmọ Joiaribu ati Jakini;
11. Seraaya, ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí ilé Ọlọrun,