18. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní ìlú mímọ́ náà jẹ́ ọrinlerugba ó lé mẹrin (284).
19. Àwọn aṣọ́nà ni, Akubu, Talimoni ati àwọn arakunrin wọn, àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ mejilelaadọsan-an (172).
20. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yòókù, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà ní àwọn ìlú Juda, kaluku sì ń gbé orí ilẹ̀ ìní rẹ̀.
21. Ṣugbọn àwọn iranṣẹ tẹmpili ń gbé ilẹ̀ Ofeli, Siha ati Giṣipa sì ni olórí wọn.
22. Usi ni alabojuto àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu. Usi yìí jẹ́ ọmọ Bani, ọmọ Haṣabaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mika, lára àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin. Òun ni olùdarí ìsìn ninu ilé Ọlọrun.