Mika 4:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ó bá yá, a óo fìdí òkè ilé OLUWA múlẹ̀bí òkè tí ó ga jùlọ,a óo gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ,àwọn eniyan yóo sì máa wọ́ wá sibẹ.

2. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé,“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA,ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.”Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde,ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu.

3. Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè,ati láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbára ní ọ̀nà jíjìn réré;wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́,wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé;àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.

Mika 4