6. OLUWA ní, “Nítorí náà, n óo sọ Samaria di àlàpà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, yóo di ọgbà ìgbin àjàrà sí; gbogbo òkúta tí a fi kọ́ ọ ni n óo fọ́nká, sinu àfonífojì, ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo sì hàn síta.
7. Gbogbo ère oriṣa rẹ̀ ni a óo fọ́ túútúú, a óo sì jó gbogbo owó iṣẹ́ àgbèrè rẹ̀ níná. Gbogbo ère rẹ̀ ni n óo kójọ bí òkítì, a óo sì kọ̀ wọ́n tì; nítorí pé owó àgbèrè ni ó fi kó wọn jọ, ọrọ̀ rẹ̀ yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a ṣe àgbèrè.
8. “Nítorí èyí, n óo sọkún, n óo sì pohùnréré ẹkún; n óo rìn káàkiri ní ìhòòhò láìwọ bàtà. N óo máa ké kiri bí ọ̀fàfà, n óo sì ṣọ̀fọ̀ bí ẹyẹ ògòǹgò.
9. Nítorí pé egbò Samaria kò lè ṣe é wò jinná; egbò náà sì ti ran Juda, ó ti dé ẹnubodè àwọn eniyan mi, àní, Jerusalẹmu.”
10. Ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ìṣubú wa ní ìlú Gati, ẹ má sọkún rárá; ẹ̀yin ará ìlú Beti Leafira, ẹ máa gbé ara yílẹ̀.
11. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Ṣafiri ẹ máa rìn ní ìhòòhò pẹlu ìtìjú lọ sí ìgbèkùn. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Saanani, ẹ má jáde kúrò níbẹ̀, nítorí ẹkún àwọn ará Beteseli, yóo fihàn yín pé kò sí ààbò yín lọ́dọ̀ wọn.
12. Àwọn ará Marotu ń retí ire pẹlu gbogbo ọkàn wọn, nítorí pé ibi ti dé sí bodè Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ OLUWA.
13. Ẹ̀yin ará Lakiṣi, ẹ de kẹ̀kẹ́ ogun yín mọ́ ẹṣin; ọ̀dọ̀ yín ni ẹ̀ṣẹ̀ ti kọ́ bẹ̀rẹ̀, tí ó sì tàn lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu, nítorí pé nípasẹ̀ yín ni Israẹli ṣe dẹ́ṣẹ̀.
14. Nítorí náà, ẹ óo fún àwọn ará Moreṣeti Gati ní ẹ̀bùn ìdágbére; ilé Akisibu yóo sì jẹ́ ohun ìtànjẹ fún àwọn ọba Israẹli.
15. Ẹ̀yin ará Mareṣa, n óo tún jẹ́ kí àwọn ọ̀tá borí yín; ògo Israẹli yóo sì lọ sí ọ̀dọ̀ Adulamu.