Matiu 27:49-56 BIBELI MIMỌ (BM)

49. Ṣugbọn àwọn yòókù ń sọ pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí a wò bí Elija yóo wá gbà á là.”

50. Jesu bá tún kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀, ó bá dákẹ́.

51. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn òkè sán.

52. Òkúta ẹnu ibojì ṣí, a sì jí ọ̀pọ̀ òkú àwọn olódodo dìde.

53. Wọ́n jáde kúrò ninu ibojì lẹ́yìn tí Jesu ti jí dìde, wọ́n wọ Jerusalẹmu lọ, ọpọlọpọ eniyan ni ó rí wọn.

54. Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”

55. Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin wà níbẹ̀ tí wọ́n dúró ní òkèèrè réré, tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ni wọ́n tí ń tẹ̀lé Jesu láti Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un.

56. Maria Magidaleni wà lára wọn, ati Maria ìyá Jakọbu ati ti Josẹfu ati ìyá àwọn ọmọ Sebede.

Matiu 27