12. Nígbà náà ni ó wá yé wọn pé kì í ṣe ti ìwúkàrà tí à ń fi sinu burẹdi ni ó ń sọ, ti ẹ̀kọ́ àwọn Farisi ati Sadusi ni ó ń sọ.
13. Nígbà tí Jesu dé agbègbè ìlú Kesaria ti Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé Ọmọ-Eniyan jẹ́?”
14. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni. Àwọn mìíràn ní Elija ni. Àwọn mìíràn tún ní Jeremaya ni tabi ọ̀kan ninu àwọn wolii.”
15. Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?”
16. Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun Alààyè.”
17. Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run.
18. Mo sọ fún ọ pé: Peteru ni ọ́, ní orí àpáta yìí ni n óo kọ́ ìjọ mi lé; agbára ikú kò ní lè ká a.
19. N óo fún ọ ní kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run. Ohunkohun tí o bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run. Ohunkohun tí o bá sì tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run.”
20. Nígbà náà ni Jesu wá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Mesaya.
21. Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí máa fihan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé dandan ni kí òun lọ sí Jerusalẹmu, kí òun jìyà pupọ lọ́wọ́ àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin; ati pé kí wọ́n pa òun, ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí òun dìde.
22. Ni Peteru bá pè é sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “Ọlọrun má jẹ́! Oluwa, irú èyí kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ.”
23. Ṣugbọn Jesu yipada, ó sọ fún Peteru pé, “Kó ara rẹ̀ kúrò níwájú mi, Satani. Ohun ìkọsẹ̀ ni o jẹ́ fún mi, nítorí o kò ro nǹkan ti Ọlọrun, ti eniyan ni ò ń rò.”