32. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, sibẹ nígbà tí ó bá dàgbà, a tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ. A di igi, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run óo wá ṣe ìtẹ́ wọn lára ẹ̀ka rẹ̀.”
33. Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.”
34. Jesu sọ gbogbo nǹkan wọnyi fún àwọn eniyan ní òwe. Kò sọ ohunkohun fún wọn láì lo òwe;
35. kí ọ̀rọ̀ tí wolii ti sọ lè ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé,“Bí òwe bí òwe ni ọ̀rọ̀ mi yóo jẹ́.N óo sọ àwọn ohun tí ó ti wà ní àṣírí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.”
36. Nígbà tí Jesu kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, ó lọ sinu ilé. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé, “Ṣe àlàyé òwe èpò inú oko fún wa.”
37. Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó fúnrúgbìn rere ni Ọmọ-Eniyan.
38. Ayé ni oko tí ó fúnrúgbìn sí. Irúgbìn rere ni àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ọmọ èṣù.
39. Ọ̀tá tí ó fọ́n èpò ni èṣù. Ìkórè ni ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli ni olùkórè.
40. Nítorí náà, bí wọn tíí kó èpò jọ tí wọn ń sun ún ninu iná, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé.