11. Ibikíbi tí wọn kò bá ti gbà yín, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí láti kìlọ̀ fún wọn.”
12. Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ti ń lọ, wọ́n ń waasu pé kí gbogbo eniyan ronupiwada.
13. Wọ́n ń lé ọpọlọpọ ẹ̀mí èṣù jáde, wọ́n ń fi òróró pa ọpọlọpọ aláìsàn lára, wọ́n sì ń mú wọn lára dá.
14. Hẹrọdu ọba gbọ́ nípa Jesu, nítorí òkìkí rẹ̀ kàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó jí dìde ninu òkú, òun ni ó jẹ́ kí ó lè máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀.”
15. Ṣugbọn àwọn mìíràn ń wí pé, “Elija ni.”Àwọnmìíràn ní, “Wolii ni, bí ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́.”
16. Ṣugbọn nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ó ní, “Johanu tí mo ti bẹ́ lórí ni ó jí dìde.”
17. Nítorí Hẹrọdu kan náà yìí ni ó ranṣẹ lọ mú Johanu tí ó fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi iyawo Filipi arakunrin Hẹrọdu tí Hẹrọdu gbà.
18. Nítorí Johanu a máa wí fún Hẹrọdu pé, “Kò yẹ fún ọ láti gba iyawo arakunrin rẹ.”
19. Nítorí náà Hẹrọdiasi ní Johanu sinu, ó fẹ́ pa á, ṣugbọn kò lè pa á,
20. nítorí Hẹrọdu bẹ̀rù Johanu, nítorí ó mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni ati pé kò ní àléébù. Nítorí náà ó dáàbò bò ó. Ọkàn Hẹrọdu a máa dàrú gidigidi nígbàkúùgbà tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, sibẹ a máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
21. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Hẹrọdiasi rí àkókò tí ó wọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Hẹrọdu se àsè ọjọ́ ìbí rẹ̀, ó pe àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀gágun, ati àwọn eniyan pataki ilẹ̀ Galili.