13. Ó bá rán meji ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín, ẹ tẹ̀lé e.
14. Kí ẹ sọ fún baálé ilé tí ó bá wọ̀ pé, ‘Olùkọ́ni wí pé yàrá wo ni ààyè wà fún mi, níbi tí èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ti lè jẹ àsè Ìrékọjá?’
15. Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín, ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí wọn ti tọ́jú sílẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.”
16. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ, wọ́n wọ inú ìlú, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn; wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.
17. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Jesu wá sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.
18. Bí wọ́n ti jókòó tí wọn ń jẹun, Jesu ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín tí ń bá mi jẹun nisinsinyii ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”
19. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dààmú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Àbí èmi ni?”
20. Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ọ̀kan ninu ẹ̀yin mejeejila ni, tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ pẹlu mi ninu àwo kan náà.
21. Nítorí Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.”
22. Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó fún wọn. Ó ní, “Ẹ gbà, èyí ni ara mi.”
23. Ó tún mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá gbé e fún wọn. Gbogbo wọn mu ninu rẹ̀.
24. Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ọpọlọpọ eniyan.
25. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé n kò ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ tí n óo mu ún ní ọ̀tun ninu ìjọba Ọlọrun.”
26. Lẹ́yìn tí wọ́n kọ orin tán, wọ́n jáde lọ sí Òkè Olifi.
27. Jesu bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, àwọn aguntan yóo bá fọ́nká,’
28. Ṣugbọn lẹ́yìn tí a bá ti jí mi dìde, n óo ṣiwaju yín lọ sí Galili.”
29. Ṣugbọn Peteru wí fún un pé, “Bí gbogbo eniyan bá pada lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní pada.”
30. Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ní alẹ́ yìí kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ náà yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”
31. Ṣugbọn Peteru tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Bí ó bá kan ọ̀ràn pé kí n bá ọ kú, sibẹ n kò ní sẹ́ ọ!”Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń wí.