Luku 13:11-20 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Obinrin kan wà tí ó ní irú ẹ̀mí èṣù kan tí ó sọ ọ́ di aláìlera fún ọdún mejidinlogun. Ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀, kò lè nàró dáradára.

12. Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é, ó sọ fún un pé, “Obinrin yìí, a wò ọ́ sàn kúrò ninu àìlera rẹ.”

13. Jesu bá gbé ọwọ́ mejeeji lé e. Lẹsẹkẹsẹ ni ẹ̀yìn rẹ̀ bá nà, ó bá ń fi ògo fún Ọlọrun.

14. Ṣugbọn inú bí olórí ilé ìpàdé nítorí Jesu ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ó bá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ọjọ́ mẹfa wà tí a níláti fi ṣiṣẹ́. Ẹ wá fún ìwòsàn láàrin àwọn ọjọ́ mẹfa yìí. Ẹ má wá fún ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi mọ́!”

15. Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin alágàbàgebè! Èwo ninu yín ni kì í tú mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ibùjẹ ẹran kí ó lọ fún un ní omi ní Ọjọ́ Ìsinmi?

16. Ẹ wá wo obinrin yìí, ọmọ Abrahamu, tí Satani ti dè fún ọdún mejidinlogun. Ṣé kò yẹ kí á tú u sílẹ̀ ninu ìdè yìí ní Ọjọ́ Ìsinmi?”

17. Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ báyìí, ojú ti gbogbo àwọn tí ó takò o. Ńṣe ni inú gbogbo àwọn eniyan dùn nítorí gbogbo ohun ìyanu tí ó ń ṣe.

18. Nítorí náà Jesu sọ pé, “Kí ni à bá fi ìjọba Ọlọrun wé? Kí ni ǹ bá fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19. Ó dàbí ẹyọ wóró musitadi kan, tí ẹnìkan mú, tí ó gbìn sí oko rẹ̀. Nígbà tí ó bá dàgbà, ó di igi, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run wá ń ṣe ìtẹ́ wọn sí orí ẹ̀ka rẹ̀.”

20. Ó tún sọ pé, “Kí ni ǹ bá fi ìjọba Ọlọrun wé?

Luku 13