Luku 1:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n ti kọ ìròyìn lẹ́sẹẹsẹ, nípa ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ láàrin wa;

2. àwọn tí nǹkan wọnyi ṣojú wọn, tí wọ́n sì sọ fún wa.

3. Mo ti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ohun gbogbo fínnífínní. Èmi náà wá pinnu láti kọ ìwé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ, ọlọ́lá jùlọ, Tiofilu,

4. kí o lè mọ òtítọ́ àwọn nǹkan tí wọ́n kọ́ ọ.

5. Ní àkókò Hẹrọdu, ọba Judia, alufaa kan wà tí ń jẹ́ Sakaraya, ní ìdílé Abiya. Orúkọ iyawo rẹ̀ ni Elisabẹti, láti inú ìdílé Aaroni.

6. Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà.

7. Ṣugbọn wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Elisabẹti yàgàn. Àwọn mejeeji ni wọ́n sì ti di arúgbó.

8. Nígbà tí ó yá, ó kan ìpín àwọn Sakaraya láti wá ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú Ọlọrun ninu Tẹmpili.

9. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn alufaa, Sakaraya ni ìbò mú láti sun turari ninu iyàrá Tẹmpili Oluwa.

10. Gbogbo àwọn eniyan ń gbadura lóde ní àkókò tí ó ń sun turari.

Luku 1