5. “Ẹ mú ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, kí ẹ sì fi ṣe burẹdi mejila, ìdámárùn-ún ìwọ̀n ìyẹ̀fun efa kan ni kí ẹ fi ṣe burẹdi kọ̀ọ̀kan.
6. Ẹ sì máa tò wọ́n kalẹ̀ sí ọ̀nà meji; mẹfa mẹfa ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, lórí tabili tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe.
7. Ẹ fi ojúlówó turari sí ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lè fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA gẹ́gẹ́ bí àmì fún ìrántí.
8. Ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, Aaroni yóo máa tò wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA nígbà gbogbo, ní orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu títí lae.