Lefitiku 23:6-16 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kan náà sì ni àjọ àìwúkàrà OLUWA. Ọjọ́ meje gbáko ni ẹ gbọdọ̀ fi máa jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà.

7. Ní ọjọ́ kinni, ẹ níláti ní àpèjọ, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó bá lágbára.

8. Ṣugbọn, ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA fún ọjọ́ meje náà, ọjọ́ àpèjọ mímọ́ ni ọjọ́ keje yóo jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó lágbára.”

9. OLUWA tún rán Mose pé kí ó

10. sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí n óo fun yín, tí ẹ bá sì ń kórè nǹkan inú rẹ̀, ẹ níláti gbé ìtí ọkà kan lára àkọ́so oko yín tọ alufaa lọ.

11. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keji, lẹ́yìn ọjọ́ ìsinmi, alufaa yóo fi ìtí ọkà náà rú ẹbọ fífì níwájú OLUWA, kí ẹ lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.

12. Ní ọjọ́ tí ẹ bá ń fi ìtí ọkà yín rú ẹbọ fífì, kí ẹ fi ọ̀dọ́ akọ aguntan ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

13. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu rẹ̀ nìyí: ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí wọ́n fi òróró pò, ẹ óo fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA, kí ẹ sì fi idamẹrin ìwọ̀n hini ọtí waini rú ẹbọ ohun mímu pẹlu rẹ̀.

14. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tabi ọkà, kì báà jẹ́ ọkà yíyan tabi tútù títí di ọjọ́ yìí, tí ẹ óo fi mú ẹbọ Ọlọrun yín wá, ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún ìrandíran yín, ní gbogbo ilẹ̀ yín.

15. “Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi tí ẹ mú ìtí ọkà fún ẹbọ fífì wá fún OLUWA.

16. Ẹ óo ka aadọta ọjọ́ títí dé ọjọ́ keji ọjọ́ ìsinmi keje, lẹ́yìn náà, ẹ óo mú ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ fi ọkà titun ṣe wá fún OLUWA.

Lefitiku 23