7. Nítorí pé alufaa jẹ́ ẹni mímọ́ fún Ọlọrun rẹ̀, kò gbọdọ̀ gbé aṣẹ́wó ní iyawo, tabi obinrin tí ó ti di aláìmọ́, tabi obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.
8. Ẹ gbọdọ̀ ka alufaa sí ẹni mímọ́, nítorí òun ni ó ń rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun yín. Ó níláti jẹ́ ẹni mímọ́ fun yín, nítorí pé èmi OLUWA tí mo yà yín sí mímọ́ jẹ́ mímọ́.
9. Ọmọ alufaa lobinrin, tí ó bá sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa ṣíṣe àgbèrè káàkiri, sọ baba rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí náà sísun ni kí ẹ dáná sun ọmọ náà.
10. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ alufaa àgbà láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n ti ta òróró sí lórí láti yà á sọ́tọ̀, kí ó lè máa wọ àwọn aṣọ mímọ́, kò gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ rí játijàti; kò sì gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya, láti fi hàn pé ó ń ṣọ̀fọ̀.
11. Kò gbọdọ̀ lọ sí ibi tí wọ́n bá tẹ́ òkú sí, tabi kí ó sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, kì báà jẹ́ òkú baba rẹ̀ tabi ti ìyá rẹ̀.
12. Kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ninu ibi mímọ́ náà, tabi kí ó sọ ibi mímọ́ Ọlọrun rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí pé, òróró ìyàsímímọ́ Ọlọrun rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Èmi ni OLUWA.
13. Obinrin tí kò bá tíì mọ ọkunrin rí ni ó gbọdọ̀ fẹ́ níyàwó.
14. Kò gbọdọ̀ fi opó ṣe aya tabi obinrin tí ó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, tabi obinrin tí ó ti mọ ọkunrin, tabi aṣẹ́wó; kò gbọdọ̀ fẹ́ èyíkéyìí ninu wọn. Obinrin tí kò tíì mọ ọkunrin rí ni kí ó fẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
15. Kí ó má baà sọ àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìmọ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé èmi ni OLUWA, tí mo sọ ọ́ di mímọ́.”