Lefitiku 20:21-24 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Bí ọkunrin kan bá bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lòpọ̀, tabi aya àbúrò rẹ̀, ohun àìmọ́ ni, ohun ìtìjú ni ó sì ṣe sí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ̀, àwọn mejeeji yóo kú láì bímọ.

22. “Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ kíyèsí gbogbo àwọn ìlànà mi ati àwọn òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ilẹ̀ tí mò ń ko yín lọ má baà tì yín jáde.

23. Ẹ kò sì gbọdọ̀ kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo lé jáde fun yín, nítorí pé tìtorí gbogbo ohun tí wọn ń ṣe wọnyi ni mo fi kórìíra wọn.

24. Ṣugbọn mo ti ṣèlérí fun yín pé, ẹ̀yin ni ẹ ó jogún ilẹ̀ wọn, n óo fi ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, tí ó sì ń ṣàn fún wàrà ati oyin fun yín, gẹ́gẹ́ bí ohun ìní. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo eniyan.

Lefitiku 20