1. “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mú ọkà wá siwaju OLUWA láti fi rúbọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró ati turari sórí rẹ̀.
2. Kí ó gbé e tọ àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, lọ, kí alufaa náà bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu ìyẹ̀fun náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀. Ẹ̀kúnwọ́ kan yìí ni alufaa yóo sun fún ìrántí, ẹbọ olóòórùn dídùn, tí a fi iná sun sí OLUWA.
3. Ohun tí ó ṣẹ́kù ninu ìyẹ̀fun náà di ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Òun ló mọ́ jùlọ, nítorí pé apá kan ninu ẹbọ sísun sí OLUWA ni.
4. “Bí ó bá jẹ́ pé ohun jíjẹ tí a yan lórí ààrò ni ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu rẹ̀. Ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò ni wọ́n gbọdọ̀ fi yan án, ó sì lè jẹ́ burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu tí a da òróró lé lórí.