19. “Nígbà tí obinrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, kí ó wà ní ipò àìmọ́ fún ọjọ́ meje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kàn án jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
20. Ohunkohun tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, tabi tí ó jókòó lé lórí ní gbogbo àkókò àìmọ́ rẹ̀ yóo di aláìmọ́.
21. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
22. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
23. Kì báà jẹ́ ibùsùn rẹ̀ ni, tabi ohunkohun tí ó fi jókòó ni eniyan bá fi ara kàn, ẹni náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
24. Bí ọkunrin kan bá bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, ọkunrin náà yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje, ibùsùn tí ọkunrin náà bá sì dùbúlẹ̀ lé lórí yóo jẹ́ aláìmọ́.
25. “Bí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára obinrin fún ọpọlọpọ ọjọ́, tí kì í sì í ṣe àkókò nǹkan oṣù rẹ̀, tabi tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá dà kọjá iye ọjọ́ tí ó yẹ kí ó dà, ó jẹ́ aláìmọ́ ní gbogbo àkókò tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lára rẹ̀. Yóo jẹ́ aláìmọ́ bí ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.
26. Ibùsùn tí ó bá dùbúlẹ̀ lé lórí, ní gbogbo ọjọ́ tí nǹkan yìí bá fi ń dà lára rẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́; ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.
27. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ara kan ibùsùn tabi ìjókòó rẹ̀, yóo di aláìmọ́; kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
28. Ṣugbọn nígbà tí ẹ̀jẹ̀ náà bá dá, kí ó ka ọjọ́ meje lẹ́yìn ọjọ́ náà; lẹ́yìn náà, ó di mímọ́.
29. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹjọ, kí ó mú àdàbà meji, tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa lọ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
30. Kí alufaa fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, kí ó sì fi ekeji rú ẹbọ sísun, kí ó ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ohun àìmọ́ tí ó jáde lára rẹ̀.