64. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo àwọn ìlú ńláńlá pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.
65. Wọ́n tún ṣẹ́ gègé láti fún wọn ní àwọn ìlú ńláńlá tí a dárúkọ wọnyi lára ìlú àwọn ẹ̀yà Juda, Simeoni ati ti Bẹnjamini.
66. Lára ilẹ̀ ẹ̀yà Efuraimu ni wọ́n ti pín àwọn ìlú ńláńlá fún àwọn ìdílé kan ninu àwọn ọmọ Kohati.
67. Àwọn ìlú ààbò tí wọ́n fún wọn, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká, ní agbègbè olókè Efuraimu nìwọ̀nyí; Ṣekemu, ati Geseri;
68. Jokimeamu ati Beti Horoni;
69. Aijaloni ati Gati Rimoni.
70. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, wọ́n fún ìdílé àwọn ọmọ Kohati tí ó kù ní Aneri ati Bileamu, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.
71. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìlú wọnyi, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká: Golani ní ilẹ̀ Baṣani, ati Aṣitarotu.
72. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari; wọ́n fún wọn ní Kedeṣi ati Daberati;
73. Ramoti ati Anemu, pẹlu àwọn pápá oko àyíká wọn.