Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, wọ́n fún ìdílé àwọn ọmọ Kohati tí ó kù ní Aneri ati Bileamu, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.