52. baba Meraiotu, baba Amaraya, baba Ahitubu;
53. baba Sadoku, baba Ahimaasi.
54. Ilẹ̀ tí a pín fún ìran Aaroni nìyí, pẹlu ààlà wọn: ìdílé Kohati ni a kọ́kọ́ pín ilẹ̀ fún ninu àwọn ọmọ Lefi.
55. Wọ́n fún wọn ní ìlú Heburoni ní ilẹ̀ Juda, ati gbogbo ilẹ̀ pápá oko tí ó yí i ká,
56. ṣugbọn Kalebu ọmọ Jefune ni wọ́n fún ní ìgbèríko ati ìletò tí ó yí ìlú Heburoni ká.
57. Àwọn ọmọ Aaroni ni a pín àwọn ìlú ààbò wọnyi fún: Heburoni, Libina, Jatiri ati Eṣitemoa, pẹlu àwọn pápá oko tí ó yí wọn ká.
58. Bẹ́ẹ̀ náà ni Hileni, ati Debiri,
59. ati Aṣani ati Beti Ṣemeṣi pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká.
60. Àwọn ìlú tí wọ́n pín fún wọn, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini nìwọ̀nyí: Geba, Alemeti, ati Anatoti, pẹlu pápá oko tí ó yí wọn ká. Gbogbo àwọn ìlú tí ó jẹ́ tiwọn ní gbogbo ìdílé wọn jẹ́ mẹtala.