27. Ṣimei bí ọmọkunrin mẹrindinlogun ati ọmọbinrin mẹfa. Ṣugbọn àwọn arakunrin rẹ̀ kò bí ọmọ pupọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà rẹ̀ kò pọ̀ bí ẹ̀yà Juda.
28. Àwọn ìran Simeoni ní ń gbé àwọn ìlú wọnyi títí di àkókò ọba Dafidi: Beeriṣeba, Molada, ati Hasariṣuali.
29. Biliha, Esemu, ati Toladi;
30. Betueli, Horima, ati Sikilagi;
31. Beti Makabotu, Hasasusimu, Betibiri, ati Ṣaaraimu.
32. Àwọn ìletò wọn ni: Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni ati Aṣani,
33. àwọn ìlú marun-un pẹlu àwọn ìgbèríko tí ó yí wọn ká títí dé ìlú Baali. Àwọn agbègbè náà ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì ní àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.