22. ati Jokimu, ati àwọn ará ìlú Koseba, Joaṣi ati Sarafu, tí wọ́n fi ìgbà kan jẹ́ alákòóso ní Moabu, tí wọ́n sì pada sí Bẹtilẹhẹmu. (Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ti àtijọ́.)
23. Wọ́n jẹ́ amọ̀kòkò ní ààfin ọba, wọ́n sì ń gbé ìlú Netaimu ati Gedera.
24. Simeoni ni baba Nemueli, Jamini, Jaribu, Sera, ati Ṣaulu.
25. Ṣaulu bí Ṣalumu, Ṣalumu bí Mibisamu, Mibisamu sì bí Miṣima.
26. Àwọn ọmọ Miṣima nìyí: Hamueli, Sakuri, ati Ṣimei.
27. Ṣimei bí ọmọkunrin mẹrindinlogun ati ọmọbinrin mẹfa. Ṣugbọn àwọn arakunrin rẹ̀ kò bí ọmọ pupọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà rẹ̀ kò pọ̀ bí ẹ̀yà Juda.
28. Àwọn ìran Simeoni ní ń gbé àwọn ìlú wọnyi títí di àkókò ọba Dafidi: Beeriṣeba, Molada, ati Hasariṣuali.
29. Biliha, Esemu, ati Toladi;
30. Betueli, Horima, ati Sikilagi;
31. Beti Makabotu, Hasasusimu, Betibiri, ati Ṣaaraimu.
32. Àwọn ìletò wọn ni: Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni ati Aṣani,
33. àwọn ìlú marun-un pẹlu àwọn ìgbèríko tí ó yí wọn ká títí dé ìlú Baali. Àwọn agbègbè náà ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì ní àkọsílẹ̀ ìdílé wọn.
34. Meṣobabu, Jamileki, ati Joṣa, jẹ́ ọmọ Amasaya;
35. Joẹli, ati Jehu, ọmọ Joṣibaya, ọmọ Seraaya, ọmọ Asieli.
36. Elioenai, Jaakoba, ati Jeṣohaya; Asaya, Adieli, Jesimieli ati Bẹnaya;
37. Sisa, ọmọ Ṣifi, ọmọ Aloni, ọmọ Jedaaya, ọmọ Ṣimiri, ọmọ Ṣemaaya.
38. Gbogbo wọn jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, ìdílé àwọn baba wọn sì pọ̀ lọpọlọpọ.
39. Wọ́n rìn títí dé ẹnubodè Gedori, ní apá ìlà oòrùn àfonífojì, láti wá koríko fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.