5. Balogun kẹta, tí ó wà fún oṣù kẹta ni Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, alufaa. Iye àwọn tí ó wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
6. Bẹnaya yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọgbọ̀n akọni jagunjagun, òun sì ni olórí wọn. Amisabadi ọmọ rẹ̀ ni ó ń ṣe àkóso ìpín rẹ̀.
7. Asaheli, arakunrin Joabu, ni balogun fún oṣù kẹrin. Sebadaya, ọmọ rẹ̀, ni igbákejì rẹ̀. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
8. Balogun tí ó wà fún oṣù karun-un ni Ṣamuhutu, láti inú ìran Iṣari; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).