Kronika Kinni 24:6-20 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ṣemaaya, akọ̀wé, ọmọ Netaneli, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó kọ orúkọ wọn sílẹ̀ níwájú ọba ati àwọn ìjòyè, ati Sadoku, alufaa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati àwọn baálé baálé ninu ìdílé àwọn alufaa, ati ti àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n bá ti mú ọ̀kan láti inú ìran Eleasari, wọn á sì tún mú ọ̀kan láti ìran Itamari.

7. Gègé tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ mú Jehoiaribu, ekeji mú Jedaaya. Gègé sì mú àwọn yòókù wọnyi tẹ̀léra wọn báyìí:

8. Harimu, Seorimu;

9. Malikija, Mijamini;

10. Hakosi, Abija,

11. Jeṣua, Ṣekanaya;

12. Eliaṣibu, Jakimu,

13. Hupa, Jeṣebeabu;

14. Biliga, Imeri,

15. Hesiri, Hapisesi;

16. Petahaya, Jehesikeli,

17. Jakini, Gamuli;

18. Delaaya, Maasaya.

19. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n óo ṣe tẹ̀léra wọn níbi iṣẹ́ ṣíṣe ninu ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Aaroni, baba wọn, ti là sílẹ̀ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun pa fún Israẹli.

20. Àwọn olórí ninu ìdílé àwọn ọmọ Lefi yòókù nìwọ̀nyí: Ṣubaeli láti inú ìdílé Amramu,Jedeaya láti inú ìdílé Ṣubaeli.

Kronika Kinni 24