2. Dafidi sọ fún Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pé, “Ẹ lọ ka àwọn ọmọ Israẹli láti Beeriṣeba títí dé Dani, kí ẹ wá fún mi lábọ̀, kí n lè mọ iye wọn.”
3. Ṣugbọn Joabu dáhùn pé, “Kí Ọlọrun jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ síi ní ìlọ́po ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un, ju iye tí wọ́n jẹ́ nisinsinyii lọ! Kabiyesi, ṣebí abẹ́ ìwọ oluwa mi ni gbogbo wọn wà? Kí ló wá dé tí o fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ló dé tí o fi fẹ́ mú àwọn ọmọ Israẹli jẹ̀bi?”
4. Ṣugbọn ti ọba ni ó ṣẹ, Joabu bá lọ kà wọ́n jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Israẹli, ó sì pada wá sí Jerusalẹmu.
5. Joabu fún ọba ní iye àwọn ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ marundinlọgọta (1,100,000) ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, ati ọ̀kẹ́ mẹtalelogun ó lé ẹgbaarun (470,000) ninu àwọn ẹ̀yà Juda.
6. Nítorí pé àṣẹ tí ọba pa yìí burú lójú Joabu, kò ka àwọn ẹ̀yà Lefi ati ti Bẹnjamini.
7. Inú Ọlọrun kò dùn sí ọ̀rọ̀ náà, nítorí náà ó jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà.
8. Dafidi bá sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, níti ohun tí mo ṣe yìí. Mo sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ji èmi iranṣẹ rẹ, nítorí pé ìwà òmùgọ̀ ni mo hù.”
9. Ọlọrun bá rán Gadi, aríran Dafidi pé,
10. “Lọ sọ fún Dafidi pé, ‘OLUWA ní, nǹkan mẹta ni òun fi siwaju rẹ, kí o yan èyí tí o bá fẹ́ kí òun ṣe sí ọ ninu wọn.’ ”
11. Gadi bá lọ sọ́dọ̀ Dafidi ó lọ sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o yan èyí tí o bá fẹ́ ninu àwọn nǹkan mẹta wọnyi:
12. yálà kí ìyàn mú fún ọdún mẹta, tabi kí àwọn ọ̀tá rẹ máa lé ọ kiri, kí wọ́n sì máa fi idà pa yín fún oṣù mẹta, tabi kí idà OLUWA kọlù ọ́ fún ọjọ́ mẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn sọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ náà, kí angẹli Ọlọrun sì máa paniyan jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Sọ èyí tí o bá fẹ́, kí n lè mọ ohun tí n óo sọ fún ẹni tí ó rán mi.”
13. Nígbà náà ni Dafidi wí fún Gadi pé, “Ìdààmú ńlá dé bá mi, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Ọlọrun, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀; má jẹ́ kí n bọ́ sí ọwọ́ eniyan.”
14. Nítorí náà, Ọlọrun rán àjàkálẹ̀ àrùn sórí ilẹ̀ Israẹli, àwọn tí wọ́n kú sì jẹ́ ẹgbaa marundinlogoji (70,000) eniyan.