25. Jerameeli, àkọ́bí Hesironi, bí ọmọkunrin marun-un: Ramu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Buna, Oreni, Osemu, ati Ahija.
26. Jerameeli tún ní aya mìíràn, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara, òun ni ìyá Onamu.
27. Àwọn ọmọ Ramu, àkọ́bí Jerameeli ni: Maasi, Jamini ati Ekeri.
28. Onamu bí ọmọ meji: Ṣamai ati Jada. Ṣamai náà bí ọmọ meji: Nadabu ati Abiṣuri.
29. Orúkọ aya Abiṣuri ni Abihaili, ó sì bí Ahibani ati Molidi fún un.
30. Nadabu, arakunrin Abiṣuri náà bí ọmọ meji: Seledi ati Apaimu; ṣugbọn Seledi kò bímọ títí tí ó fi kú.
31. Apaimu ni baba Iṣi. Iṣi bí Ṣeṣani, Ṣeṣani sì bí Ahilai.
32. Jada, arakunrin Ṣamai, bí ọmọ meji: Jeteri ati Jonatani, ṣugbọn Jeteri kò bímọ títí tí ó fi kú.
33. Jonatani bí ọmọ meji: Peleti ati Sasa. Àwọn ni ìran Jerameeli.
34. Ṣeṣani kò bí ọmọkunrin kankan, kìkì ọmọbinrin ni ó bí; ṣugbọn Ṣeṣani ní ẹrú kan, ará Ijipti, tí ń jẹ́ Jariha.