Kronika Kinni 19:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nítorí náà, Hanuni mú àwọn oníṣẹ́ Dafidi, ó fá irùngbọ̀n wọn, ó gé ẹ̀wù wọn ní ìbàdí, ó sì lé wọn jáde.

5. Ojú tì wọ́n pupọ wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró sí Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, lẹ́yìn náà kí wọ́n máa pada bọ̀ wá sílé.

6. Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé Dafidi ti kórìíra àwọn, Hanuni ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ẹgbẹrun (1,000) talẹnti fadaka ranṣẹ sí Mesopotamia, ati sí Aramu-maaka ati sí Soba, láti yá kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin.

7. Wọ́n yá ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ọba Maaka pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n wá, wọ́n sì pàgọ́ ogun wọn sí ẹ̀bá Medeba. Àwọn ará Amoni náà wá kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ láti gbogbo ìlú wọn.

8. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó rán Joabu ati gbogbo àwọn akọni jagunjagun rẹ̀ jáde lọ bá wọn.

9. Àwọn ogun Amoni tò lẹ́sẹẹsẹ siwaju ẹnubodè ìlú wọn, ṣugbọn àwọn ọba tí wọ́n bẹ̀ lọ́wẹ̀ wà lọ́tọ̀ ninu pápá.

Kronika Kinni 19