Wọ́n yá ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ọba Maaka pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n wá, wọ́n sì pàgọ́ ogun wọn sí ẹ̀bá Medeba. Àwọn ará Amoni náà wá kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ láti gbogbo ìlú wọn.