10. Nígbà tí Joabu rí i pé àwọn ọ̀tá ti gbógun ti òun níwájú ati lẹ́yìn, ó yan àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli láti dojú kọ àwọn ará Siria.
11. Ó fi àwọn ọmọ ogun yòókù sí abẹ́ Abiṣai, arakunrin rẹ̀, wọ́n sì dojú kọ àwọn ọmọ ogun Amoni.
12. Joabu ní, “Bí àwọn ọmọ ogun Siria bá lágbára jù fún mi, wá ràn mí lọ́wọ́, bí ó bá sì jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Amoni ni wọ́n bá lágbára jù fún ọ, n óo wá ràn ọ́ lọ́wọ́.
13. Ṣe ọkàn rẹ gírí, jẹ́ kí á jà gidigidi fún àwọn eniyan wa, ati fún àwọn ìlú Ọlọrun wa; kí OLUWA ṣe ohun tí ó bá dára lójú rẹ̀.”
14. Joabu ati àwọn ogun Israẹli súnmọ́ àwọn ọmọ ogun Siria láti bá wọn jà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Siria sá fún wọn.