13. Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé e lákọ̀ọ́kọ́, OLUWA Ọlọrun wa jẹ wá níyà, nítorí pé a kò tọ́jú rẹ̀ bí ó ti tọ́.”
14. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli.
15. Àwọn ọmọ Lefi fi ọ̀pá gbé e lé èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Mose.
16. Dafidi pàṣẹ fún àwọn olórí ninu àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n yan àwọn akọrin láàrin ara wọn, tí wọn yóo máa fi ohun èlò orin bíi hapu, dùùrù, ati aro dá orin ayọ̀.
17. Nítorí náà àwọn ọmọ Lefi yan Hemani, ọmọ Joẹli ati Asafu, arakunrin rẹ̀, ọmọ Berekaya, ati àwọn arakunrin wọn láti ìdílé Merari, arakunrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaaya.
18. Wọ́n yan àwọn arakunrin wọn wọnyi kí wọ́n wà ní ipò keji sí wọn: Sakaraya, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Uni, Eliabu, Bẹnaya, Maaseaya, Matitaya, Elifelehu ati Mikineiya, pẹlu àwọn aṣọ́nà: Obedi Edomu ati Jeieli.
19. Wọ́n yan àwọn akọrin, Hemani, Asafu ati Etani láti máa lu aro tí wọ́n fi idẹ ṣe
20. Sakaraya, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Uni, Eliabu, Maaseaya ati Bẹnaya ń lo hapu,
21. ṣugbọn Matitaya, Elifelehu, Mikineiya, Obedi Edomu, Jeieli ati Asasaya ni wọ́n ń tẹ dùùrù.
22. Kenanaya ni a yàn láti máa darí orin àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé ó ní ìmọ̀ orin.
23. Berekaya ati Elikana ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.
24. Àwọn alufaa tí wọ́n yàn láti máa fọn fèrè níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun ni: Ṣebanaya, Joṣafati, Netaneli, Amasa, Sakaraya, Bẹnaya, ati Elieseri. Obedi Edomu ati Jehaya pẹlu ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ibi tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu sí.
25. Dafidi ati àwọn àgbààgbà Israẹli ati àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun bá lọ sí ilé Obedi Edomu, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ayọ̀.