15. Nígbà tí o bá ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi balisamu ni kí o kọlù wọ́n, nítorí pé n óo ṣáájú rẹ lọ láti kọlu ogun Filistini.”
16. Dafidi ṣe ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún un, wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Gibeoni títí dé Gasa.
17. Òkìkí Dafidi kàn káàkiri, OLUWA sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ̀ máa ba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.