Kronika Kinni 11:25-42 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Ó di olókìkí láàrin àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun; ṣugbọn òkìkí tirẹ̀ kò tó ti àwọn akọni mẹta náà. Dafidi bá fi ṣe olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba.

26. Àwọn olókìkí mìíràn ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí: Asaheli, arakunrin Joabu; ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu;

27. Ṣamotu, láti Harodu;

28. Helesi, láti inú ìdílé Peloni, Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa, ati Abieseri, láti Anatoti

29. Sibekai, láti inú ìdílé Huṣati, ati Ilai, láti inú ìdílé Aho;

30. Maharai, ará Netofa, ati Helodi, ọmọ Baana, ará Netofa;

31. Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ati Bẹnaya, ará Piratoni;

32. Hurai, ará etí odò Gaaṣi, ati Abieli, ará Aribati;

33. Asimafeti, ará Bahurumu, ati Eliaba ará Ṣaaliboni;

34. Haṣemu, ará Gisoni, ati Jonatani, ọmọ Ṣagee, ará Harari;

35. Ahiamu, ọmọ Sakari, ará Harari, ati Elifali, ọmọ Uri;

36. Heferi, ará Mekerati, ati Ahija, ará Peloni;

37. Hesiro, ará Kamẹli, ati Naarai ọmọ Esibai;

38. Joẹli, arakunrin Natani, ati Mibihari, ọmọ Hagiri,

39. Seleki, ará Amoni, ati Naharai, ará Beeroti, tí ń ru ihamọra Joabu ọmọ Seruaya.

40. Ira, ará Itiri, ati Garebu ará Itiri,

41. Uraya, ará Hiti, ati Sabadi, ọmọ Ahilai,

42. Adina, ọmọ Ṣisa, láti inú ẹ̀yà Reubẹni, olórí kan láàrin ẹ̀yà Reubẹni, pẹlu ọgbọ̀n àwọn ọmọ ogun rẹ̀;

Kronika Kinni 11