25. Ó di olókìkí láàrin àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun; ṣugbọn òkìkí tirẹ̀ kò tó ti àwọn akọni mẹta náà. Dafidi bá fi ṣe olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba.
26. Àwọn olókìkí mìíràn ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí: Asaheli, arakunrin Joabu; ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu;
27. Ṣamotu, láti Harodu;
28. Helesi, láti inú ìdílé Peloni, Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa, ati Abieseri, láti Anatoti
29. Sibekai, láti inú ìdílé Huṣati, ati Ilai, láti inú ìdílé Aho;
30. Maharai, ará Netofa, ati Helodi, ọmọ Baana, ará Netofa;
31. Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ati Bẹnaya, ará Piratoni;
32. Hurai, ará etí odò Gaaṣi, ati Abieli, ará Aribati;