10. Wọ́n kó àwọn ihamọra rẹ̀ sinu tẹmpili oriṣa wọn, wọ́n sì kan orí Saulu mọ́ ara ògiri tẹmpili Dagoni, oriṣa wọn.
11. Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi Gileadi gbọ́ bí àwọn ará Filistia ti ṣe Saulu,
12. gbogbo àwọn akọni ọkunrin tí wọ́n gbóyà gidigidi gbéra, wọ́n lọ gbé òkú Saulu ati òkú àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí Jabeṣi, wọ́n sì sin egungun wọn sí abẹ́ igi oaku ní Jabeṣi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje.
13. Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ṣe kú nítorí aiṣododo rẹ̀; ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, ó sì lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ abókùúsọ̀rọ̀, ó lọ bèèrè ìtọ́sọ́nà níbẹ̀,
14. dípò kí ó bèèrè ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ OLUWA. Nítorí náà, OLUWA pa á, ó sì gbé ìjọba rẹ̀ fún Dafidi, ọmọ Jese.