Kronika Keji 4:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Solomoni ọba ṣe pẹpẹ idẹ kan tí ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).

2. Ó ṣe agbada omi kan tí ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½), ó sì ga ní igbọnwọ marun-un (mita 2¼). Àyíká etí rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 13½).

3. Gbogbo ẹ̀yìn agbada yìí ni ó ya àwòrán mààlúù sí ní ìlà meji meji yíká ìsàlẹ̀ etí rẹ̀.

4. Agbada yìí wà lórí ère mààlúù mejila tí wọ́n kọjú síta: mẹta kọjú sí ìhà àríwá, mẹta kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹta kọjú sí ìhà gúsù, mẹta yòókù sì kọjú sí ìlà oòrùn.

5. Agbada náà nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ dàbí etí ife omi ati bí òdòdó lílì. Agbada náà gbà tó ẹgbẹẹdogun ìwọ̀n bati omi.

Kronika Keji 4