18. Àwọn ará Filistia ti gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati ní agbègbè Nẹgẹbu, ní Juda. Wọ́n jagun gba Beti Ṣemeṣi, Aijaloni, ati Gederotu, wọ́n sì gba Soko, Timna, ati Gimso pẹlu àwọn ìletò ìgbèríko wọn, wọ́n bá ń gbé ibẹ̀.
19. OLUWA rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi, ọba Juda, nítorí pé ó hùwà ìríra ní Juda, ó sì ṣe aiṣootọ sí OLUWA.
20. Nítorí náà Tigilati Pileseri, ọba Asiria gbógun ti Ahasi, ó sì fìyà jẹ ẹ́, dípò kí ó ràn án lọ́wọ́.
21. Ahasi kó ohun ìṣúra inú ilé OLUWA, ati ti ààfin, ati ti inú ilé àwọn ìjòyè, ó fi san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria, sibẹsibẹ ọba Asiria kò ràn án lọ́wọ́.
22. Ní àkókò ìyọnu Ahasi ọba, ó túbọ̀ ṣe alaiṣootọ sí OLUWA ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.
23. Ó rúbọ sí àwọn oriṣa àwọn ará Damasku tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn oriṣa àwọn ọba Siria ràn wọ́n lọ́wọ́, n óo rúbọ sí wọn kí wọ́n lè ran èmi náà lọ́wọ́.” Ṣugbọn àwọn oriṣa ọ̀hún ni wọ́n fa ìparun bá òun ati orílẹ̀-èdè rẹ̀.
24. Gbogbo ohun èlò ilé Ọlọrun ni Ahasi gé wẹ́wẹ́, ó sì ti ìlẹ̀kùn ibẹ̀; ó wá tẹ́ pẹpẹ oriṣa káàkiri Jerusalẹmu.
25. Ó ṣe ibi ìrúbọ káàkiri àwọn ìlú Juda níbi tí yóo ti máa sun turari sí àwọn oriṣa. Nípa bẹ́ẹ̀, ó mú OLUWA Ọlọrun àwọn baba rẹ̀ bínú.
26. Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, wà ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati ti Israẹli.