Kronika Keji 24:15-21 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Nígbà tí Jehoiada dàgbà tí ó di arúgbó, ó kú nígbà tí ó pé ẹni aadoje (130) ọdún.

16. Wọ́n sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi nítorí iṣẹ́ rere tí ó ṣe ní Israẹli fún Ọlọrun ati ní ilé mímọ́ rẹ̀.

17. Ṣugbọn nígbà tí Jehoiada kú, àwọn ìjòyè ní Juda wá kí ọba, wọ́n sì júbà rẹ̀, ó sì gba ìmọ̀ràn wọn.

18. Wọ́n kọ ilé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń sin oriṣa Aṣera ati àwọn ère mìíràn. Nítorí ìwà burúkú yìí, inú bí OLUWA sí Juda ati Jerusalẹmu.

19. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA rán àwọn wolii sí wọn láti darí wọn pada sọ́dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ fún wọn, wọ́n kọ etí dídi sí àwọn wolii.

20. Nígbà tí ó yá, Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Sakaraya, ọmọ Jehoiada alufaa, ó bá dìde dúró láàrin àwọn eniyan, ó ní, “Ọlọrun ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi tàpá sí òfin òun OLUWA; ṣé ẹ kò fẹ́ kí ó dára fun yín ni? Nítorí pé, ẹ ti kọ OLUWA sílẹ̀, òun náà sì ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ”

21. Ṣugbọn wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, ọba pàṣẹ pé kí wọn sọ ọ́ lókùúta pa ninu gbọ̀ngàn ilé OLUWA.

Kronika Keji 24