13. Gbogbo àwọn tí wọ́n kópa ninu iṣẹ́ náà fi tagbára tagbára ṣe é. Iṣẹ́ náà tẹ̀síwájú títí tí wọ́n fi tún ilé OLUWA náà ṣe tán, tí ó sì rí bíi ti iṣaaju tí ó sì tún lágbára sí i.
14. Nígbà tí wọ́n tún ilé OLUWA náà ṣe tán, wọ́n kó owó tí ó kù pada sọ́dọ̀ ọba ati Jehoiada. Wọ́n fi owó náà ṣe àwọn ohun èlò fún ìsìn ati ẹbọ sísun ní ilé OLUWA, ati àwo fún turari ati ohun èlò wúrà ati fadaka.Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé OLUWA lojoojumọ, ní gbogbo àkókò Jehoiada.
15. Nígbà tí Jehoiada dàgbà tí ó di arúgbó, ó kú nígbà tí ó pé ẹni aadoje (130) ọdún.
16. Wọ́n sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi nítorí iṣẹ́ rere tí ó ṣe ní Israẹli fún Ọlọrun ati ní ilé mímọ́ rẹ̀.
17. Ṣugbọn nígbà tí Jehoiada kú, àwọn ìjòyè ní Juda wá kí ọba, wọ́n sì júbà rẹ̀, ó sì gba ìmọ̀ràn wọn.