17. Ẹ kò ní jagun rárá, ẹ sá dúró ní ààyè yín, kí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo sì rí bí OLUWA yóo ti gba ẹ̀yin ará Juda ati Jerusalẹmu là. Ẹ má fòyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì, Ẹ lọ kò wọ́n lójú lọ́la, OLUWA yóo wà pẹlu yín.”
18. Jehoṣafati dojúbolẹ̀, gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.
19. Ni àwọn ọmọ Lefi láti inú ìdílé Kohati ati ti Kora bá dìde, wọ́n gbóhùn sókè, wọ́n sì yin OLUWA Ọlọrun Israẹli.
20. Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà lọ sí aṣálẹ̀ Tekoa. Bí wọ́n ti ń lọ, Jehoṣafati dúró, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, ẹ gba ohun tí àwọn wolii rẹ̀ wí gbọ́ pẹlu, ẹ óo sì ní ìṣẹ́gun.”