Kọrinti Kinni 4:19-21 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ṣugbọn mò ń bọ̀ láìpẹ́, bí Oluwa bá fẹ́. N óo wá mọ agbára tí àwọn tí wọn ń gbéraga ní nígbà náà, yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn lásán.

20. Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu: ti agbára ni!

21. Kí ni ẹ fẹ́? Kí n tọ̀ yín wá pẹlu pàṣán ni, tabi pẹlu ẹ̀mí ìfẹ́ ati ní ìrẹ̀lẹ̀?

Kọrinti Kinni 4