4. wọ́n lo ọgbọ́n, wọ́n tọ́jú oúnjẹ, wọ́n mú àwọn àpò ìdọ̀họ tí wọ́n ti gbó, wọ́n dì wọ́n lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Wọ́n mú awọ ìpọnmi tí ó ti gbó, tí wọ́n sì ti lẹ̀,
5. wọ́n wọ sálúbàtà tí ó ti gbó ati aṣọ àkísà, gbogbo oúnjẹ tí wọn mú lọ́wọ́ ni ó ti gbẹ, tí ó sì ti bu.
6. Wọ́n tọ Joṣua lọ ninu àgọ́ tí ó wà ní Giligali, wọ́n wí fún òun ati àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ọ̀nà jíjìn ni a ti wá, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á dá majẹmu.”
7. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí fún àwọn ará Hifi náà pé, “Bóyá nítòsí ibí ni ẹ ti wá, báwo ni a ṣe lè ba yín dá majẹmu?”
8. Wọ́n sọ fún Joṣua pé “Iranṣẹ yín ni wá.”Joṣua bá dá wọn lóhùn pé, “Ta ni yín, níbo ni ẹ sì ti wá?”
9. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ọ̀nà jíjìn ni àwa iranṣẹ rẹ ti wá nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, nítorí a ti gbúròó rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti,
10. ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, Sihoni ọba àwọn ará Heṣiboni ati Ogu ọba àwọn ará Baṣani tí ń gbé Aṣitarotu.”