Joṣua 15:2-12 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ààlà ilẹ̀ wọn, ní ìhà gúsù lọ láti òpin Òkun Iyọ̀,

3. láti apá etí òkun tí ó kọjú sí ìhà gúsù lọ títí dé àtigun òkè Akirabimu. Ó lọ títí dé Sini, ó tún lọ sí apá gúsù Kadeṣi Banea. Ó kọjá lọ lẹ́bàá Hesironi títí dé Adari, kí ó tó wá yípo lọ sí ìhà Kaka.

4. Lẹ́yìn náà, ó lọ títí dé Asimoni, ó tọ ipa odò Ijipti, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Òun ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ Juda ní apá ìhà gúsù.

5. Òkun Iyọ̀ ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn, ó lọ títí dé ibi tí odò Jọdani ti ń ṣàn wọ inú òkun.Níbẹ̀ ni ààlà rẹ̀ ní apá àríwá ti bẹ̀rẹ̀,

6. ó lọ títí dé Beti Hogila, ó lọ dé ìhà àríwá Betaraba, ó tún lọ títí dé ibi òkúta Bohani ọmọ Reubẹni.

7. Ó lọ láti àfonífojì Akori títí dé Debiri, ó wá yípo lọ sí apá ìhà àríwá, lọ sí Giligali, tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, tí ó wà ní apá gúsù àfonífojì náà. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ibi odò Enṣemeṣi, ó sì pin sí Enrogeli.

8. Ààlà náà tún lọ sí apá òkè, sí àfonífojì ọmọ Hinomu ní apá gúsù òkè àwọn ará Jebusi (tíí ṣe ìlú Jerusalẹmu). Ó tún lọ títí dé orí òkè náà, tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní òpin ìhà àríwá àfonífojì Refaimu.

9. Láti ibẹ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ láti orí òkè títí dé odò Nefitoa, ó lọ sí apá ibi tí àwọn ìlú ńláńlá wà lẹ́bàá òkè Efuroni, ó wá pada sí apá Baala (tí a tún ń pè ní Kiriati Jearimu.)

10. Ààlà náà tún yípo lọ sí ìwọ̀ oòrùn Baala, sí apá òkè Seiri, lọ sí apá ìhà àríwá òkè Jearimu (tí a tún ń pè ní Kesaloni), ó bá tún dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sí Beti Ṣemeṣi títí dé ìkọjá Timna.

11. Ó tún gba ti àwọn òkè tí ó wà ní ìhà àríwá Ekironi, ó wá yípo lọ sí Ṣikeroni. Lẹ́yìn náà, ó kọjá lọ sí òkè Baala títí dé Jabineeli, ó wá lọ parí sí Òkun Mẹditarenia.

12. Òkun yìí ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.Òun ni ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Joṣua 15