12. Òkun yìí ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.Òun ni ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
13. Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua, ó fún Kalebu ọmọ Jefune ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀ ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda. Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba, (tí a tún ń pè ní ìlú Ariba), Ariba yìí ni baba Anaki.
14. Kalebu lé àwọn ìran Anaki mẹtẹẹta jáde níbẹ̀, àwọn ni ìran Ṣeṣai, ìran Ahimani, ati ìran Talimai.
15. Láti ibẹ̀ ó lọ gbógun ti àwọn ará ìlú Debiri. Orúkọ Debiri tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Seferi.
16. Kalebu ṣe ìlérí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹgun Kiriati Seferi tí ó sì gba ìlú náà ni òun yóo fún ní Akisa ọmọ òun, láti fi ṣe aya.
17. Otinieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, ni ó ṣẹgun ìlú náà. Kalebu bá fi Akisa ọmọ rẹ̀ fún un láti fi ṣe aya.
18. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ó rọ ọkọ rẹ̀ pé kí ó tọrọ ilẹ̀ kan lọ́wọ́ baba òun. Ní ọjọ́ kan, bí Akisa ti sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, baba rẹ̀ bi í pé, “Kí ni ò ń fẹ́?”