Johanu 9:31-41 BIBELI MIMỌ (BM)

31. A mọ̀ pé Ọlọrun kì í fetí sí ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn a máa fetí sí ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

32. Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé a kò rí i gbọ́ pé ẹnikẹ́ni la ojú ẹni tí wọ́n bí ní afọ́jú rí.

33. Bí ọkunrin yìí kò bá wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, kì bá tí lè ṣe ohunkohun.”

34. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ìwọ yìí tí wọ́n bí ninu ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n tọ́ dàgbà ninu ẹ̀ṣẹ̀, o wá ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́!” Wọ́n bá tì í jáde.

35. Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ti ọkunrin náà jáde kúrò ninu ilé ìpàdé. Nígbà tí ó rí i, ó bí i pé, “Ìwọ gba Ọmọ-Eniyan gbọ́ bí?”

36. Ọkunrin náà dáhùn pé, “Alàgbà, ta ni ẹni náà, kí n lè gbà á gbọ́?”

37. Jesu wí fún un pé, “Èmi tí ò ń wò yìí, tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni ẹni náà.”

38. Ọkunrin náà dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́, Oluwa!” Ó bá dọ̀bálẹ̀ fún un.

39. Jesu bá ní, “Kí n lè ṣe ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran, kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”

40. Farisi wà láàrin àwọn eniyan tí ó wà pẹlu rẹ̀, tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n bi í pé, “Àbí àwa náà fọ́jú?”

41. Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ fọ́jú, ẹ kò bá tí ní ẹ̀bi. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ sọ pé, ‘Àwa ríran’ ẹ̀bi yín wà sibẹ.”

Johanu 9