27. Ẹ má ṣe làálàá nítorí oúnjẹ ti yóo bàjẹ́, ṣugbọn ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ọmọ eniyan yóo fun yín, tí yóo wà títí di ìyè ainipẹkun, nítorí ọmọ eniyan ni Ọlọrun Baba fún ní àṣẹ.”
28. Wọ́n wá bi í pé, “Kí ni kí á ṣe kí á lè máa ṣe iṣẹ́ Ọlọrun?”
29. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni pé kí ẹ gba ẹni tí ó rán gbọ́.”
30. Wọ́n wá bi í pé, “Iṣẹ́ ìyanu wo ni ìwọ óo ṣe, tí a óo rí i, kí á lè gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo ni o óo ṣe?
31. Àwọn baba wa jẹ mana ní aṣálẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá jẹ.’ ”
32. Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe Mose ni ó fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá. Baba mi ni ó ń fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá;
33. nítorí oúnjẹ Ọlọrun ni ẹni tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó ń fi ìyè fún aráyé.”
34. Wọ́n bá sọ fún un pé, “Alàgbà, máa fún wa ní oúnjẹ yìí nígbà gbogbo.”
35. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae.
36. Ṣugbọn mo wí fun yín pé ẹ̀yin ti rí mi, sibẹ ẹ kò gbàgbọ́.
37. Gbogbo ẹni tí Baba ti fi fún mi yóo wá sọ́dọ̀ mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, n kò ní ta á nù;
38. nítorí pé mo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ ti ara mi, bíkòṣe láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.