Johanu 5:38-46 BIBELI MIMỌ (BM)

38. Ẹ kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé inú yín nítorí ẹ kò gba ẹni tí ó rán níṣẹ́ gbọ́.

39. Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́ káàkiri nítorí pé ẹ rò pé ẹ óo rí ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun ninu rẹ̀. Ẹ̀rí mi gan-an ni wọ́n sì ń jẹ́.

40. Sibẹ ẹ kò fẹ́ tọ̀ mí wá kí ẹ lè ní ìyè.

41. “Èmi kò wá ọlá láti ọ̀dọ̀ eniyan.

42. Ṣugbọn mo mọ̀ yín, mo sì mọ̀ pé ẹ kò ní ìfẹ́ Ọlọrun ninu yín.

43. Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò gbà mí. Ṣugbọn bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ óo gbà á.

44. Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo?

45. Ẹ má ṣe rò pé èmi ni n óo fi yín sùn níwájú Baba, Mose tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé gan-an ni yóo fi yín sùn.

46. Bí ẹ bá gba Mose gbọ́, ẹ̀ bá gbà mí gbọ́, nítorí èmi ni ọ̀rọ̀ ìwé tí ó kọ bá wí.

Johanu 5