31. “Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni mò ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi lè má jẹ́ òtítọ́.
32. Ṣugbọn ẹlòmíràn ni ó ń jẹ́rìí mi, mo sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí tí ó ń jẹ́ nípa mi.
33. Ẹ ti ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Johanu, ó sì ti jẹ́rìí òtítọ́.
34. Kì í ṣe pé dandan ni fún mi pé kí eniyan jẹ́rìí gbè mí. Ṣugbọn mo sọ èyí fun yín kí ẹ lè ní ìgbàlà.
35. Johanu dàbí fìtílà tí ó ń tàn, tí ó sì mọ́lẹ̀. Ó dùn mọ yín fún àkókò díẹ̀ láti máa yọ̀ ninu ìmọ́lẹ̀ tí ó fi fun yín.
36. Ṣugbọn mo ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Johanu lọ. Àwọn iṣẹ́ tí Baba ti fún mi pé kí n parí, àní àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, àwọn ni ẹlẹ́rìí mi pé Baba ni ó rán mi níṣẹ́.
37. Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ti jẹ́rìí mi. Ẹnikẹ́ni kò ì tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò rí i bí ó ti rí rí.
38. Ẹ kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé inú yín nítorí ẹ kò gba ẹni tí ó rán níṣẹ́ gbọ́.
39. Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́ káàkiri nítorí pé ẹ rò pé ẹ óo rí ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun ninu rẹ̀. Ẹ̀rí mi gan-an ni wọ́n sì ń jẹ́.
40. Sibẹ ẹ kò fẹ́ tọ̀ mí wá kí ẹ lè ní ìyè.
41. “Èmi kò wá ọlá láti ọ̀dọ̀ eniyan.
42. Ṣugbọn mo mọ̀ yín, mo sì mọ̀ pé ẹ kò ní ìfẹ́ Ọlọrun ninu yín.
43. Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò gbà mí. Ṣugbọn bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ óo gbà á.
44. Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo?