Johanu 4:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ ju àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu lọ; ati pé Jesu ń ṣe ìrìbọmi fún ọpọlọpọ eniyan ju Johanu lọ.

2. Ṣugbọn ṣá, kì í ṣe Jesu fúnrarẹ̀ ni ó ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni.

3. Nígbà tí Jesu mọ̀ pé àwọn Farisi ti gbọ́ ìròyìn yìí, ó kúrò ní Judia, ó tún pada lọ sí Galili.

4. Ó níláti gba ààrin ilẹ̀ Samaria kọjá.

5. Ó dé ìlú Samaria kan tí ń jẹ́ Sikari, lẹ́bàá ilẹ̀ tí Jakọbu fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀.

6. Kànga kan tí ó ní omi wà níbẹ̀, tí Jakọbu gbẹ́ nígbà ayé rẹ. Jesu jókòó létí kànga náà ní nǹkan bí agogo mejila ọ̀sán, àárẹ̀ ti mú un nítorí ìrìn àjò tí ó rìn.

7. Obinrin kan ará Samaria wá pọn omi. Jesu wí fún un pé, “Fún mi ní omi mu.”

8. (Ní àkókò yìí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ ra oúnjẹ ninu ìlú.)

9. Obinrin ará Samaria náà dá Jesu lóhùn pé, “Kí ló dé tí ìwọ tí ó jẹ́ Juu fi ń bèèrè omi lọ́wọ́ èmi tí mo jẹ́ obinrin ará Samaria?” (Gbolohun yìí jáde nítorí àwọn Juu kì í ní ohunkohun ṣe pẹlu àwọn ará Samaria.)

10. Jesu dá a lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọrun ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.”

11. Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, o kò ní ohun tí o lè fi fa omi, kànga yìí sì jìn, níbo ni ìwọ óo ti mú omi ìyè wá?

12. Ìwọ kò ṣá ju Jakọbu baba-ńlá wa, tí ó gbẹ́ kànga yìí fún wa lọ, tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹran-ọ̀sìn rẹ̀ sì ń mu níbẹ̀?”

13. Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi yìí òùngbẹ yóo tún gbẹ ẹ́.

14. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi tí èmi yóo fi fún un, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ mọ́ lae, ṣugbọn omi tí n óo fún un yóo di orísun omi ninu rẹ̀ tí yóo máa sun títí dé ìyè ainipẹkun.”

15. Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí kí òùngbẹ má baà gbẹ mí mọ́, kí n má baà tún wá pọn omi níhìn-ín mọ́.”

Johanu 4