1. Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án.
2. Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì,
3. wọ́n wá ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbá a létí.
4. Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.”
5. Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.”
6. Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ rí i, wọ́n kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”Pilatu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ kàn án mọ́ agbelebu, nítorí ní tèmi, n kò rí ẹ̀bi kankan tí ó jẹ.”
7. Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “A ní òfin kan, nípa òfin náà, ikú ni ó tọ́ sí i, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.”
8. Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á.
9. Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?”Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn.
10. Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò dá lóhùn? O kò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti dá ọ sílẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́ agbelebu?”
11. Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.”
12. Láti ìgbà náà ni Pilatu ti ń wá ọ̀nà láti dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn àwọn Juu ń kígbe pé, “Bí o bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari, gbogbo ẹni tí ó bá fi ara rẹ̀ jọba lòdì sí Kesari.”